Hebrews 8:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí gbogbo Olórí Alufaa tí a bá yàn, a yàn wọ́n pé kí wọ́n máa mú ẹ̀bùn ati ẹbọ àwọn eniyan wá siwaju Ọlọrun ni. Bákan náà ni òun náà níláti ní àwọn ohun tí yóo máa mú wá siwaju Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori a fi olukuluku olori alufa jẹ lati mã mu ẹ̀bun wá ati lati mã rubọ: nitorina olori alufa yi pẹlu kò le ṣe aini ohun ti yio fi rubọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí a fi olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan jẹ láti máa mú ẹ̀bùn wá láti máa rúbọ: Nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún eléyìí náà láti ní nǹkan tí ó máa fi sílẹ̀.