Hebrews 8:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn yìí ń ṣe ìsìn wọn ninu ilé ìsìn tí ó jẹ́ ẹ̀dà ati àfijọ ti ọ̀run. A rí i pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí nítorí nígbà tí Mose fẹ́ kọ́ àgọ́, ohun tí Ọlọrun sọ fún un ni pé, “Ṣe akiyesi pé o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí mo fihàn ọ́ ní orí òkè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹniti njọsìn fun apẹrẹ ati ojiji awọn ohun ọrun, bi a ti kọ́ Mose lati ọdọ Ọlọrun wá nigbati o fẹ pa agọ́: nitori o wipe, kiyesi ki o ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi apẹrẹ ti a fihàn ọ lori òke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹni tí ń sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ ẹ̀dá àti òjìji ohun tí ń lọ́run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mósè nígbà tí ó kọ́ àgọ́: Nítorí ó wí pé, “Kíyèsí kí o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fihàn ọ lórí òkè.”