Hebrews 8:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba wọn dá ní ọjọ́ tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nítorí wọn kò pa majẹmu mi mọ́, mo bá kẹ̀yìn sí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kì iṣe gẹgẹ bi majẹmu ti mo ti bá awọn baba wọn dá, li ọjọ na ti mo fà wọn lọwọ lati mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; nitoriti nwọn kò duro ninu majẹmu mi, emi kò si kà wọn si, ni Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì, nítorí wọn kò jẹ́ olótítọ́ sí májẹ̀mú mi èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí ni Olúwa wí.