Hebrews 9:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ọpọlọpọ ìgbà ni ìbá ti máa jìyà láti ìgbà tí a ti fi ìdí ayé sọlẹ̀. Ṣugbọn ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nígbà tí àkókò òpin dé, láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù nípa ẹbọ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí ó fi ara rẹ̀ rú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi bẹ̃kọ on kì bá ṣai mã jìya nigbakugba lati ipilẹ aiye: ṣugbọn nisisiyi li o fi ara hàn lẹ̃kanṣoṣo li opin aiye lati mu ẹ̀ṣẹ kuro nipa ẹbọ ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí bẹ́ẹ̀ bá ni oun ìbá tí máa jìyà nígbàkúgbà láti ìpìlẹ̀ ayé: Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ́kanṣoṣo lópìn ayé láti mi ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀.