Hebrews 9:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bákan náà ni Kristi, nígbà tí a ti fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ lọ, yóo tún pada lẹẹkeji, kì í ṣe láti tún ru ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ṣugbọn láti gba àwọn tí ó ń fi ìtara retí rẹ̀ là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Kristi pẹlu lẹhin ti a ti fi rubọ lẹ̃kanṣoṣo lati ru ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ, yio farahan nigbakeji laisi ẹ̀ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rẹ̀ fun igbala.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Kírísítì pẹ̀lú lẹ̀yìn tí a ti fi rúbọ lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kéjì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.