Hebrews 9:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Níbẹ̀ ni pẹpẹ wúrà wà fún sísun turari, ati àpótí majẹmu tí a fi wúrà bò yíká. Ninu àpótí yìí ni apẹ wúrà kékeré kan wà tí wọ́n fi mana sí ninu, ati ọ̀pá Aaroni tí ó rúwé nígbà kan rí, ati àwọn wàláà òkúta tí a kọ òfin mẹ́wàá sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti o ni awo turari wura, ati apoti majẹmu ti a fi wura bò yiká, ninu eyi ti ikoko wura ti o ni manna gbé wà, ati ọpá Aaroni ti o rudi, ati awọn walã majẹmu;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí májẹ̀mú tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní mánà gbé wà, àti ọ̀pá Árónì tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú;