Hebrews 9:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí a ti ṣe ṣe ètò gbogbo nǹkan wọnyi nìyí. Ninu àgọ́ àkọ́kàn ni àwọn alufaa ti máa ń ṣe wọlé-wọ̀de nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nigbati a ti ṣe ètò nkan wọnyi bayi, awọn alufa a mã lọ nigbakugba sinu agọ́ ekini, nwọn a mã ṣe iṣẹ ìsin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkúgbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn.