Hosea 1:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A óo kó àwọn eniyan Israẹli ati ti Juda papọ̀, wọn óo yan olórí kanṣoṣo fún ara wọn; wọn óo sì máa ti ibẹ̀ jáde wá. Dájúdájú, ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesireeli yóo jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni a o kó awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Israeli jọ̀ pọ̀, nwọn o si yàn olori kan fun ara wọn, nwọn o si jade kuro ni ilẹ na: nitori nla ni ọjọ Jesreeli yio jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yóò para pọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jésírẹ́lì yóò jẹ́.