Hosea 1:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Ọlọrun kọ́kọ́ bá Israẹli sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosia, Ọlọrun ní, “Lọ fẹ́ obinrin alágbèrè kan, kí o sì bí àwọn ọmọ alágbèrè; nítorí pé àwọn eniyan mi ti ṣe àgbèrè pupọ nípa pé, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibẹ̀rẹ ọ̀rọ Oluwa si Hosea. Oluwa si wi fun Hosea, pe, Lọ, fẹ́ agbère obinrin kan fun ara rẹ, ati awọn ọmọ agbère; nitori ilẹ yi ti ṣe agbère gidigidi, kuro lẹhin Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí OLÚWA bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hósíà, OLÚWA wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún araa rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ OLÚWA.”