Hosea 1:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní Jesireeli; nítorí láìpẹ́ yìí ni n óo jẹ ìdílé Jehu níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn tí ó dá ní Jesireeli, n óo sì fi òpin sí ìjọba Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ ni Jesreeli; nitori niwọ̀n igbà diẹ, emi o bẹ̀ ẹ̀jẹ Jesreeli wò li ara ile Jehu, emi o si mu ki ijọba ile Israeli kasẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Hósíà pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jésírẹ́lì, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jéhù ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jésírẹ́lì, Èmi yóò sì mú ìjọba Ísírẹ́lì wá sí òpin.