Hosea 1:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gomeri tún lóyún, ó sì bí ọmọbinrin kan. OLUWA tún sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní, ‘Kò sí Àánú’; nítorí n kò ní ṣàánú àwọn eniyan Israẹli mọ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tún loyún, o si bi ọmọbinrin kan. Ọlọrun si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ li Loruhama: nitori emi kì yio tún ma ṣãnu fun ile Israeli mọ, nitoriti emi o mu wọn kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gómérì sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. OLÚWA sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-rúhámà, nítorí pé Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Ísírẹ́lì mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n.