Hosea 1:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
n kò sì ní dáríjì wọ́n mọ́, ṣugbọn n óo fẹ́ràn ilé Juda, n óo sì ṣàánú wọn, èmi OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n là, láìlo ọfà ati ọrun, idà tabi ogun, tabi ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi o ṣãnu fun ile Juda, emi o si fi Oluwa Ọlọrun wọn gbà wọn là, emi kì yio si fi ọrun, tabi idà, tabi ogun, ẹṣin, tabi ẹlẹṣin gbà wọn là.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síbẹ̀, èmi yóò ṣàáànú fún ilé Júdà, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa OLÚWA Ọlọ́run wọn.”