Hosea 10:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli dàbí àjàrà dáradára tí ń so èso pupọ. Bí èso rẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni pẹpẹ oriṣa wọn ń pọ̀ sí i. Bí àwọn ìlú wọn tí ń dára sí i ni àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn náà ń dára sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ÁJARA ofo ni Israeli, o nso eso fun ara rẹ̀; gẹgẹ bi ọ̀pọ eso rẹ̀ li o mu pẹpẹ pọ̀ si i; gẹgẹ bi didara ilẹ rẹ̀ ni nwọn yá ere daradara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ísírẹ́lì jẹ́ igi àjàrà tó gbalé ó ń sọ èṣo fún ara rẹ̀ Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere Ó bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.