Hosea 10:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí náà, ogun yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan yín, gbogbo ibi ààbò yín ni yóo parun. Bí Ṣalimani ti pa Betabeli run, ní ọjọ́ ogun, ní ọjọ́ tí wọ́n pa ìyá tòun tọmọ;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li ariwo yio dide ninu awọn enia rẹ, gbogbo awọn odi agbara rẹ li a o si bajẹ, bi Ṣalmani ti ba Bet-abeli jẹ li ọjọ ogun: a fọ́ iya tũtũ lori awọn ọmọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín kí gbogbo odi agbára yín ba le parun. Gẹ́gẹ́ bí Ṣalìmanì ṣe pa Bétí-Ábélì run lọ́jọ́ ogun, nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn