Hosea 10:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń fọ́nnu lásán; wọ́n ń fi ìbúra asán dá majẹmu; nítorí náà ni ìdájọ́ ṣe dìde sí wọn bíi koríko olóró, ní poro oko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ti sọ ọ̀rọ, nwọn mbura eke ni didà majẹmu: bayi ni idajọ hù soke bi igi iwọ, ni aporo oko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀, wọ́n ṣe ìbúra èké, wọ́n da májẹ̀mú: báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko, bi i koríko májèlé láàrin oko tí a ro.