Hosea 10:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Samaria wárìrì fún ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, oriṣa ìlú Betafeni. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, àwọn babalóòṣà rẹ̀ yóo pohùnréré ẹkún lé e lórí, nítorí ògo rẹ̀ tí ó ti fò lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awọn ọmọ-malu Bet-afeni, awọn ti ngbe Samaria yio bẹ̀ru: nitori awọn enia ibẹ̀ yio ṣọ̀fọ lori rẹ̀, ati awọn baba-oloriṣà ibẹ̀ ti o yọ̀ lori rẹ̀, nitori ogo rẹ̀, nitori o ti lọ kuro lọdọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samáríà bẹ̀rù nítorí ere màlúù tó wà ní Bẹti-Áfẹ́nì Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀ Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí ogo rẹ̀ nítorí o tí lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.