Hosea 11:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Wọn óo pada sí ilẹ̀ Ijipti, Asiria óo sì jọba lé wọn lórí, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On kì yio yipadà si ilẹ Egipti, ṣugbọn ara Assiria ni yio jẹ ọba rẹ̀, nitori nwọn kọ̀ lati yipadà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣé wọn ò wá ní padà sí Éjíbítì bí Ṣé Ásíríà kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronú pìwàdà?