Hosea 11:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N kò ní fa ibinu yọ mọ́, n kò ní pa Efuraimu run mọ́, nítorí pé Ọlọrun ni mí, n kì í ṣe eniyan, èmi ni Ẹni Mímọ́ tí ó wà láàrin yín, n kò sì ní pa yín run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi kì yio mu gbigboná ibinu mi ṣẹ, emi kì yio yipadà lati run Efraimu: nitori Ọlọrun li emi, kì iṣe enia; Ẹni-Mimọ lãrin rẹ: emi kì yio si wá ninu ibinu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò ni i mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ tàbí kí èmi wá sọ Éfúráímù di ahoro Nítorí pé Ọlọ́run ni àni, èmi kì í ṣe ènìyàn Ẹni mímọ́ láàrin yín, Èmi kò ni i wa nínú ìbínú