Hosea 12:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Asán ati ìbàjẹ́ ni gbogbo nǹkan tí Efuraimu ń ṣe látàárọ̀ dalẹ́. Wọ́n ń parọ́ kún irọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá wọn ń pọ̀ sí i. Wọ́n ń bá àwọn Asiria dá majẹmu, wọ́n sì ń ru òróró lọ sí ilẹ̀ Ijipti.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
EFRAIMU njẹ afẹfẹ́, o si ntọ̀ afẹfẹ́ ila-õrun lẹhìn: o nmu eke ati iparun pọ̀ si i lojojumọ; nwọn si ba awọn ara Assiria da majẹmu, nwọn si nrù ororo lọ si Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Éfúráímù ń jẹ afẹ́fẹ́; Ó n lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀ oòrùn ní gbogbo ọjọ́. Ó sì ń gbèrú nínú irọ́ Ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ásíríà Ó si fi òróró ólífì ránsẹ́ sí Éjíbítì.