Hosea 12:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà wà ní Gileadi, dájúdájú yóo parun; bí wọ́n bá fi akọ mààlúù rúbọ ní Giligali, pẹpẹ wọn yóo dàbí òkúta tí a kójọ ní poro oko.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aiṣedẽde mbẹ ni Gileadi bi? nitõtọ asan ni nwọn: nwọn rubọ akọ malu ni Gilgali; nitõtọ, pẹpẹ wọn dabi ebè ni aporo oko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gílíádì ha burú bí? Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán. Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì? Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè nínú aporo oko.