Hosea 13:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Níbo ni ọba yín wà nisinsinyii, tí yóo gbà yín là? Níbo ni àwọn olórí yín wà, tí wọn yóo gbèjà yín? Àwọn tí ẹ bèèrè fún, tí ẹ ní, ‘Ẹ fún wa ní ọba ati àwọn ìjòyè.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nibo li ọba rẹ gbe wà nisisiyi ninu gbogbo ilu rẹ, ti o le gbà ọ? ati awọn onidajọ rẹ, niti awọn ti iwọ wipe; Fun mi li ọba ati awọn ọmọ-alade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níbo ni ọba rẹ gbé wà nìsisin yìí kí ó bá à le gbà ọ là? Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà, àwọn tí ẹ sọ pé, ‘Fún wa ní ọba àti ọmọ aládé’?