Hosea 13:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Israẹli tilẹ̀ rúwé bí ewéko etí odò, atẹ́gùn OLUWA láti ìlà oòrùn yóo fẹ́ wá, yóo wá láti inú aṣálẹ̀; orísun rẹ̀ yóo gbẹ, ojú odò rẹ̀ yóo sì gbẹ pẹlu; a óo kó ìṣúra ati ohun èlò olówó iyebíye rẹ̀ kúrò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi on tilẹ ṣe eleso ninu awọn arakunrin rẹ̀, afẹfẹ́ ilà-õrùn kan yio de, afẹ̃fẹ́ Oluwa yio ti aginjù wá, orisun rẹ̀ yio si gbẹ, ati oju isun rẹ̀ li a o mu gbẹ: on o bà ohun elò daradara gbogbo jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tilẹ̀ gbilẹ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀ afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn láti ọ̀dọ̀ OLÚWA yóò wá, Yóò fẹ́ wá láti inú asálẹ̀ orísun omi rẹ̀ yóò gbẹ kànga rẹ̀ yóò gbẹ pẹ̀lú olè yóò fọ́ ilé ẹrù àti gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀