Hosea 13:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Samaria ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi Ọlọrun rẹ̀, ogun ni yóo pa wọ́n, a óo ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, a óo sì la inú àwọn aboyún wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samaria yio di ahoro: nitoriti on ti ṣọ̀tẹ si Ọlọrun rẹ̀: nwọn o ti ipa idà ṣubu: a o fọ́ ọmọ wọn tũtũ, ati aboyún wọn li a o là ni inu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ará Sámáríà gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn. Wọn ó ti ipa idà ṣubú; a ó fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, A ó sì la àwọn aboyún wọn nínú.”