Hosea 13:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yá ère fún ara wọn; ère fadaka, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, Wọ́n ń sọ pé, “Ẹ wá rúbọ sí i.” Eniyan wá ń fi ẹnu ko ère mààlúù lẹ́nu!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nisisiyi, nwọn si dá ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ, nwọn si ti fi fàdakà wọn ṣe ere didà fun ara wọn, ati òriṣa ìmọ wọn: iṣẹ oniṣọnà ni gbogbo rẹ̀; nwọn wi niti wọn pe, Jẹ ki awọn enia ti nrubọ fi ẹnu kò awọn ọmọ malu li ẹnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí, wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ wọn fi fàdákà ṣe ère òrìṣà fúnra wọn ère tí a fi ọgbọ́n dá àrà sí gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà Wọn ń sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Pé, Jẹ́ kí àwọn “Ènìyàn tí ń rúbọ fi ẹnu ko àwọn màluu ni ẹnu.”