Hosea 14:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Assuru kì yio gbà wa; awa kì yio gùn ẹṣin: bẹ̃ni awa kì yio tun wi mọ fun iṣẹ ọwọ́ wa pe, Ẹnyin li ọlọrun wa: nitori lọdọ rẹ ni alainibaba gbe ri ãnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Asíríà kò le gbà wá là; A kò ní í gorí ẹsin ogun A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé ‘Àwọn ni òrìṣà wa sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe; nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.’