Hosea 14:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́n, kí ó mọ àwọn nǹkan wọnyi; kí òye rẹ̀ sì yé ẹnikẹ́ni tí ó bá lóye; nítorí pé ọ̀nà OLUWA tọ́, àwọn tí wọ́n bá dúró ṣinṣin ni yóo máa tọ̀ ọ́, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kọsẹ̀ níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tali o gbọ́n, ti o lè moye nkan wọnyi? tali o li oye, ti o le mọ̀ wọn? nitori ọ̀na Oluwa tọ́, awọn olododo yio si ma rìn ninu wọn: ṣugbọn awọn alarekọja ni yio ṣubu sinu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni ọlọgbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn. Tí tọ́ ni ọ̀nà OLÚWA àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ nìyóò kọsẹ̀ nínú wọn.