Hosea 2:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo sì fún un ní àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ pada níbẹ̀, n óo sì sọ àfonífojì Akori di Ẹnu Ọ̀nà Ìrètí. Yóo kọrin fún mi bí ó tí ń ṣe ní ìgbà èwe rẹ̀, nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Ijipti dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si fun u ni ọgbà àjara rẹ̀ lati ibẹ̀ wá, ati afonifojì Akori fun ilẹ̀kun ireti: on o si kọrin nibẹ̀, bi li ọjọ ewe rẹ̀, ati bi li ọjọ ti o jade lati ilẹ Egipti wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un, Èmi yóò fi àfonífojì Ákórì ṣe ilẹ̀kùn ìrètí fún un. Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Éjíbítì