Hosea 2:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fi ìdí àwọn eniyan mi múlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, wọn yóo sì máa bí sí i. N óo ṣàánú ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kò sí àánú’, n óo sì sọ fún ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kì í ṣe eniyan mi’ pé eniyan mi ni; òun náà yóo sì dá mi lóhùn pé, ‘Ìwọ ni Ọlọrun mi.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si gbìn i fun ara mi lori ilẹ, emi o si ṣãnu fun ẹniti kò ti ri ãnu gbà; emi o si wi fun awọn ti kì iṣe enia mi pe, Iwọ li enia mi; on o si wipe, Iwọ li Ọlọrun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ó sì gbìn-ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘àànú Gbà.’ Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’ ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”