Hosea 3:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA tún sọ fún mi pé: “Lọ fẹ́ aya tí ń ṣe àgbèrè pada, kí o fẹ́ràn rẹ̀, bí mo ti fẹ́ràn Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yipada sí ọlọrun mìíràn, wọ́n sì fẹ́ràn láti máa jẹ àkàrà tí ó ní èso resini ninu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA sí wi fun mi pe, Tun lọ, fẹ́ obinrin kan ti iṣe olùfẹ́ ọrẹ rẹ̀, ati panṣagà, gẹgẹ bi ifẹ Oluwa si awọn ọmọ Israeli, ti nwò awọn ọlọrun miràn, ti nwọn si nfẹ́ akàra eso àjara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì wí fún mi pé, “Lọ, fi ìfẹ́ hàn sí ìyàwó rẹ̀ padà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlòmíràn ti fẹ́ ẹ, tí òun sì tún jẹ́ alágbèrè. Fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ṣe fẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tẹ́lé àwọn òrìṣà tí ó sì fẹ́ràn oúnjẹ tí àwọn aláìkọlà yà sọ́tọ̀.”