Hosea 3:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo pada tọ OLUWA Ọlọrun wọn, ati Dafidi, ọba wọn lọ. Wọn yóo fi ìbẹ̀rù wá sọ́dọ̀ OLUWA, wọn yóo sì gba oore rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhìn na awọn ọmọ Israeli yio padà, nwọn o si wá Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn; nwọn o si bẹ̀ru Oluwa, ati ore rẹ̀ li ọjọ ikẹhìn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò padà láti wá OLÚWA Ọlọ́run wọn àti Dáfídì ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú OLÚWA pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún OLÚWA àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.