Hosea 4:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; OLUWA fi ẹ̀sùn kan gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé, “Kò sí òtítọ́, tabi àánú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọrun ní ilẹ̀ náà,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọmọ Israeli; nitori Oluwa ni ẹjọ kan ba awọn ara ilẹ na wi, nitoriti kò si otitọ, tabi ãnu, tabi ìmọ Ọlọrun ni ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí pé OLÚWA fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. “Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́ Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà