Hosea 4:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ igi gbígbẹ́, ọ̀pá wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wọn. Ẹ̀mí àgbèrè ẹ̀sìn ti mú wọn ṣáko, wọ́n ti kọ Ọlọrun wọn sílẹ̀ láti máa bọ ìbọkúbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia mi mbère ìmọ lọwọ igi wọn, ọpá wọn si nfi hàn fun wọn: nitori ẹmi agbère ti mu wọn ṣìna, nwọn si ti ṣe agbère lọ kuro labẹ Ọlọrun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi Ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn. Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn sìnà wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.