Hosea 4:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń rúbọ lórí òkè gíga, wọ́n ń sun turari lórí òkè kéékèèké, ati lábẹ́ igi oaku, ati igi populari ati igi terebinti, nítorí òjìji abẹ́ wọn tutù. Nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin yín ṣe di aṣẹ́wó, àwọn aya yín sì di alágbèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn rubọ lori awọn oke-nla, nwọn si sun turari lori awọn oke kékèké, labẹ igi oaku ati igi poplari ati igi ẹlmu, nitoriti ojìji wọn dara: nitorina awọn ọmọbinrin nyin yio ṣe agbère, ati awọn afẹ́sọnà nyin yio ṣe panṣagà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ń rúbọ lórí àwọn òkè ńlá, Wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré Lábẹ́ igi óákù, àti igi pópúlárì àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.