Hosea 4:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn n kò ní jẹ àwọn ọmọbinrin yín níyà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe aṣẹ́wó, tabi kí n jẹ àwọn aya yín níyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè; nítorí pé, àwọn ọkunrin yín pàápàá ń bá àwọn aṣẹ́wó lòpọ̀, wọ́n sì ń bá àwọn aṣẹ́wó ilé oriṣa rúbọ. Àwọn tí wọn kò bá ní ìmọ̀ yóo sì parun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi kì yio ba awọn ọmọbinrin nyin wi nigbati nwọn ba ṣe agbère, tabi awọn afẹ́sọnà nyin nigbati nwọn ba ṣe panṣagà: nitori nwọn yà si apakan pẹlu awọn agbère, nwọn si mba awọn panṣagà rubọ̀: nitorina awọn enia ti kò ba moye yio ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín níyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín, nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́. Wọ́n sì ń rúbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ilé òrìṣà. Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!