Hosea 4:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ ń jìyà, àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn ẹja sì ń ṣègbé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni ilẹ na yio ṣe ṣọ̀fọ, ati olukuluku ẹniti ngbé inu rẹ̀ yio rọ, pẹlu awọn ẹranko igbẹ, ati pẹlu awọn ẹiyẹ oju ọrun; a o si mu awọn ẹja inu okun kuro pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù. Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú.