Hosea 4:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan mi ń ṣègbé nítorí àìsí ìmọ̀; nítorí pé ẹ̀yin alufaa ti kọ ìmọ̀ mi sílẹ̀, èmi náà yóo kọ̀ yín ní alufaa mi. Nítorí pé ẹ ti gbàgbé òfin Ọlọrun yín, èmi náà yóo gbàgbé àwọn ọmọ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A ké awọn enia mi kuro nitori aini ìmọ: nitori iwọ ti kọ̀ ìmọ silẹ, emi o si kọ̀ ọ, ti iwọ kì yio ṣe alufa mi mọ: niwọ̀n bi iwọ ti gbagbe ofin Ọlọrun rẹ, emi pẹlu o gbagbe awọn ọmọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀ “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfìn Ọlọ́run yín sílẹ̀ Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.