Hosea 5:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí Efuraimu rí àìsàn rẹ̀, tí Juda sì rí ọgbẹ́ rẹ̀, Efuraimu sá tọ Asiria lọ, ó sì ranṣẹ sí ọba ńlá ibẹ̀. Ṣugbọn kò lè wo àìsàn Israẹli tabi kí ó wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Efraimu ri arùn rẹ̀, ti Juda si ri ọgbẹ́ rẹ̀, nigbana ni Efraimu tọ̀ ara Assiria lọ, o si ranṣẹ si ọba Jarebu; ṣugbọn on kò le mu ọ lara da, bẹ̃ni kò le wò ọgbẹ́ rẹ jiná.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà ti Éfúráímù ri àìsàn rẹ̀, tí Júdà sì rí ojú egbò rẹ̀ ni Éfúráímù bá tọ ará Síríà lọ, ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́ ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná