Hosea 5:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bíi kinniun ni n óo rí sí Efuraimu, n óo sì fò mọ́ Juda bí ọ̀dọ́ kinniun. Èmi fúnra mi ni n óo fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, n óo sì kúrò níbẹ̀. N óo kó wọn lọ, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà wọ́n sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi o dàbi kiniun si Efraimu, ati bi ọmọ kiniun si ile Juda, emi, ani emi o fàya, emi o si lọ, emi o mu lọ, ẹnikẹni kì yio si gbà a silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Éfúráímù, bí i kìnnìún ńlá sí ilé Júdà. Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ; Èmi ó gbé wọn lọ, láì sí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.