Hosea 5:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ti hùwà aiṣootọ sí OLUWA; nítorí pé wọ́n ti bí ọmọ àjèjì. Oṣù tuntun ni yóo run àtàwọn, àtoko wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ti hùwa arekerekè si Oluwa: nitori nwọn ti bi ajèji ọmọ: nisisiyi li oṣù titun yio jẹ wọn run, pẹlu ipin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí OLÚWA wọ́n sì bí àwọn ọmọ àlè. Nísinsìn yìí, ọdún oṣù tuntun wọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú pín wọn.