Hosea 6:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí àwọn ọlọ́ṣà tií ba de eniyan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa kó ara wọn jọ, láti paniyan ní ọ̀nà Ṣekemu, wọ́n ń ṣe nǹkan ìtìjú láìbìkítà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gẹgẹ bi ọwọ́ olè iti lùmọ dè enia, bẹ̃ni ẹgbẹ́ awọn alufa fohùnṣọ̀kan lati pania li ọ̀na: nitori nwọn dá ẹ̀ṣẹ nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùbá de àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀; tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣékémù, tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.