Hosea 7:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ire Israẹli eniyan mi pada, tí mo bá sì fẹ́ wò wọ́n sàn, kìkì ìwà ìbàjẹ́ Efuraimu ati ìwà ìkà Samaria ni mò ń rí; nítorí pé ìwà aiṣododo ni wọ́n ń hù. Àwọn olè ń fọ́lé, àwọn jàgùdà sì ń jalè ní ìgboro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI emi iba mu Israeli li ara dá, nigbana ni ẹ̀ṣẹ Efraimu fi ara hàn, ati ìwa-buburu Samaria; nitori nwọn ṣeké; olè si wọle, ọwọ́ olè si nkoni lode.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí èmi ìbá mú Ísírẹ́lì láradá. Ẹ̀ṣẹ̀ Éfúráímù ń farahàn ìwà búburú Ṣamáríà sì ń hàn síta Wọ́n ń ṣe èrú àwọn olè ń fọ́ ilé àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà