Hosea 7:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Wọ́n gbé, nítorí pé wọ́n ti ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun yóo kọlù wọ́n, nítorí pé wọ́n ń bá mi ṣọ̀tẹ̀! Ǹ bá rà wọ́n pada, ṣugbọn wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egbe ni fun wọn! nitori nwọn ti sá kuro lọdọ mi: iparun ni fun wọn! nitori nwọn ti ṣẹ̀ si mi: bi o tilẹ ṣepe mo ti rà wọn padà, ṣugbọn nwọn ti ṣe eké si mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi yóò rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi