Hosea 7:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń sọkún lórí ibùsùn wọn, ṣugbọn ẹkún tí wọn ń sun sí mi kò ti ọkàn wá; nítorí oúnjẹ ati ọtí waini ni wọ́n ṣe ń gbé ara ṣánlẹ̀; ọ̀tẹ̀ ni wọ́n ń bá mi ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kò si ti fi tọkàntọkàn ké pè mi, nigbati nwọn hu lori akete wọn: nwọn kó ara wọn jọ fun ọkà ati ọti-waini, nwọn si ṣọ̀tẹ si mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn, Ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùn réré ẹkún lórí ibùsùn wọn. Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.