Hosea 7:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n yipada sí oriṣa Baali, wọ́n dàbí ọrun tí ó wọ́, idà ni a óo fi pa àwọn olórí wọn, nítorí ìsọkúsọ ẹnu wọn. Nítorí náà, wọn óo ṣẹ̀sín ní ilẹ̀ Ijipti.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn yipadà, ṣugbọn kì iṣe si Ọga-ogo: nwọn dàbi ọrun ẹtàn; awọn ọmọ-alade wọn yio tipa idà ṣubu, nitori irúnu ahọn wọn: eyi ni yio ṣe ẹsín wọn ni ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá ògo; Wọ́n dàbí ọrun tí ó wà fún ìtànjẹ́ Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú nítorí irúnú ahọ́n wọn. Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Éjíbítì.