Hosea 7:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Alágbèrè ni gbogbo wọn; wọ́n dàbí iná ààrò burẹdi tí ó gbóná, tí ẹni tí ń ṣe burẹdi kò koná mọ́, láti ìgbà tí ó ti po ìyẹ̀fun títí tí ìyẹ̀fun náà fi wú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo nwọn ni panṣagà, bi ãrò ti alakàra mu gboná, ti o dawọ́ kikoná duro, lẹhìn igbati o ti pò iyẹ̀fun tan, titi yio fi wú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Alágbèrè ni gbogbo wọn wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà tí o dáwọ́ kíkọná dúró, lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò iyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.