Hosea 8:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Àwọn ọmọ Israẹli ti gbàgbé Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì ti kọ́ ààfin fún ara wọn. Àwọn ọmọ Juda ti kọ́ ọpọlọpọ ìlú olódi sí i; ṣugbọn n óo sọ iná sí àwọn ìlú wọn, yóo sì jó àwọn ibi ààbò wọn ní àjórun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Israeli ti gbagbe Ẹlẹda rẹ̀, o si kọ́ tempili pupọ; Juda si ti sọ ilu olodi di pupọ̀: ṣugbọn emi o rán iná kan si ori awọn ilu rẹ̀, yio si jẹ awọn ãfin rẹ̀ wọnni run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí Ísírẹ́lì ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀ Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀ Júdà ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀ ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”