Hosea 9:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA wí pé: “Mo rí Israẹli he bí ìgbà tí eniyan rí èso àjàrà he ninu aṣálẹ̀. Lójú mi, àwọn baba ńlá yín dàbí èso tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kọ́ so ní àkókò àkọ́so rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí sí mi, ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé òkè Baali Peori, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún oriṣa Baali, wọ́n sì di ohun ẹ̀gbin, bí oriṣa tí wọ́n fẹ́ràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo ri Israeli bi eso ajara li aginjù; mo ri awọn baba nyin bi akọpọ́n ninu igi ọpọ̀tọ li akọso rẹ̀: ṣugbọn nwọn tọ̀ Baal-peori lọ, nwọn si yà ara wọn si itiju nì; ohun irira wọn si ri gẹgẹ bi nwọn ti fẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí mo rí Ísírẹ́lì, Ó dàbí ìgbà tí ènìyàn rí èso àjàrà ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ Nígbà tí mo rí àwọn baba yín. Ó dàbí ìgbà tí ènìyàn rí àkọ́so èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Baali-Péórì Wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni wọ́n di aláìmọ́ bí ohun tí wọ́n fẹ́ràn.