Hosea 9:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Gbogbo ìwà burúkú wọn wà ní Giligali, ibẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra wọn. Nítorí iṣẹ́ burúkú wọn, n óo lé wọn jáde ní ilé mi. N kò ní fẹ́ràn wọn mọ́, ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo àwọn olórí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ìwa-buburu wọn mbẹ ni Gilgali; nitori nibẹ̀ ni mo korira wọn; nitori ìwa-buburu iṣe wọn, emi o le wọn kuro ni ile mi, emi kì yio fẹràn wọn mọ́; gbogbo ọmọ-alade wọn ni ọlọ̀tẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gílígálì Mo kórìírà wọn níbẹ̀, Nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.