Hosea 9:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn kò ní rú ẹbọ ohun mímu sí OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ wọn kò ní tẹ́ ẹ lọ́rùn. Oúnjẹ wọn yóo dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, àwọn tí wọ́n bá jẹ ninu rẹ̀ yóo di aláìmọ́. Ebi nìkan ni oúnjẹ wọn yóo wà fún, wọn kò ní mú wá fi rúbọ lára rẹ̀ ní ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio ta Oluwa li ọrẹ ọti-waini, bẹ̃ni nwọn kì yio mu u ni inu dùn: ẹbọ wọn yio ri fun wọn bi onjẹ awọn ti nṣọ̀fọ; gbogbo awọn ti o jẹ ninu rẹ̀ ni yio di alaimọ́: nitori onjẹ wọn kì yio wá si ile Oluwa fun ọkàn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún OLÚWA. Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn. Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́. Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn kò ńi wá sí orí tẹ́ḿpìlì OLÚWA