Hosea 9:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo fọ́nká lọ sí Asiria; Ijipti ni yóo gbá wọn jọ, Memfisi ni wọn yóo sin wọ́n sí, Ẹ̀gún ọ̀gàn ni yóo hù bo àwọn nǹkan èlò fadaka olówó iyebíye wọn, ẹ̀gún yóo sì hù ninu àgọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori, sa wò o, nwọn ti lọ nitori ikogun: Egipti yio kó wọn jọ, Memfisi yio sin wọn: ibi didara fun fadakà wọn li ẹgún-ọ̀gan yio jogun wọn: ẹgún yio wà ninu agọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun Éjíbítì yóò kó wọn jọ, Mémúfísì yóò sì sin wọ́n. Ibi ìsọjọ̀ sílífa wọn ni yèrèpè yóò jogún, Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn. Ẹ̀gún yóò sì bo gbogbo àgọ́ wọn.